Ísíkẹ́lì 41:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Lẹ́yìn èyí ní ó wá wọn ilé Ọlọ́run: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ìta gbangba ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ilé àti ògiri rẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn.

14. Ibú ìta gbangba ilé Ọlọ́run ní ìhà ìlà òòrùn, papọ̀ mọ́ iwájú ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

15. Ó wá wọn gígùn ilé tí ó dojúkọ gbangba ìta ní agbègbè ilé Ọlọ́run papọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. Ìta ibi mímọ́, inú ibi mímọ́ náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìta gbangba,

16. àti pẹ̀lú àwọn ìloro ilé àti àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè yípo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, gbogbo rẹ̀ ní ìta papọ̀ mọ́ ìloro ilé ni wọ́n fi igi bò. Ilẹ̀ ògiri sókè títí dé ojú fèrèsé ni wọ́n fi igi bò pátapáta.

Ísíkẹ́lì 41