Ísíkẹ́lì 33:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ kí ó sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí mo bá fi idà kọlu ilẹ̀ kan, tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin wọn láti jẹ́ alóre wọn,

3. tí ó sì rí i pé idà ń bọ̀ lórí ilẹ̀ náà, tí ó sì fọn ìpè láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn,

4. nígbà náà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ìpè ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ ìkìlọ̀, tí idà náà wá tí ó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.

Ísíkẹ́lì 33