17. Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ ìjì rẹ̀, àwọn àjòjì rẹ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.
18. “ ‘Èwo lára igi Édẹ́nì ní a lè fi wé ọ ní dídán àti ọlá ńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Édẹ́nì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárin àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.“ ‘Èyí yìí ní Fáráò àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”