Ísíkẹ́lì 30:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.

8. Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítìtí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.

9. “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.

10. “ ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọnènìyàn Éjíbítì láti ọwọ́ Nébukadinésárì ọba Bábílónì.

Ísíkẹ́lì 30