1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé:
2. “Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Pohùnréré ẹkún kí o sì wí pé,“Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”
3. Nítorí ọjọ́ náà sún mọ́ tòsíàní ọjọ́ Olúwa sún mọ́ tòsíỌjọ́ tí ọjọ́ ìkùukùu ṣú dúdú,àsìkò ìparun fún àwọn aláìkọlà