5. Èmi yóò sọ ọ́ nù sí ihàìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:ìwọ yóò ṣubú sí gbangba okoa kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.Èmi ti fi ọ ṣe oùnjẹ fún àwọn ẹranko igbóàti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.
6. Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ijíbítì yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Ísírẹ́lì.
7. Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.
8. “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: kéyèsí i Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.
9. Ilẹ̀ Éjíbítì yóò di ihà àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Náílì; Èmi ni mo ṣe é,”
10. Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ Éjíbítì di píparun àti ahoro, pátapáta, láti Mígídólì lọ dé Ásíwánì, dé ààlà ilẹ Kúṣì.
11. Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún.