13. “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Éjíbítì jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí.
14. Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Éjíbítì padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Pátírósì, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.
15. Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹ̀lẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, ti wọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.
16. Éjíbítì kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Ísírẹ́lì mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedédé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.’ ”