1. Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹ́wàá, ọdún kẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
2. “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Fáráò ọba Éjíbítì kí ó sì sọ àṣọ̀tẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Éjíbítì.
3. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Fáráò ọba Éjíbítììwọ dírágónì ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ síàárin àwọn odò ṣíṣàn rẹèyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Náílì;èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”