6. “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run
7. Èmi yóò mú kí àwọn àjòjì dìde sí ọ,ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀ èdè;wọn yóò yọ idà wọn sí ọẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹwọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
8. Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá sínú ihòìwọ yóò sì kú ikú gbígbónáàwọn tí a pa ní àárin òkun.
9. Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́
10. Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlàní ọwọ́ àwọn àjòjìÈmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”
11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
12. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náào kún fún ọgbọ́n,o sì pé ní ẹwà