Ísíkẹ́lì 28:18-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá látiinú rẹ, yóò sì jó ọ run,èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

19. Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ní ẹnu ń yà sí ọ;ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”

20. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

21. “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sídónì; kí o sì ṣọtẹ́lẹ̀ sí i

22. Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì,a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ.Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní Olúwa,Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹtí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,

23. Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹèmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹpẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

24. “ ‘Kì yóò sì sí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.

Ísíkẹ́lì 28