19. Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdárọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jérúsálẹ́mù.
20. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánúnganran jọ sínú iná ìléru láti fi amúbí ina yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunnú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárin ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.
21. Èmi o ko yín jọ, èmi o sì fín iná ibínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrin rẹ̀.
22. Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò se yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”
23. Lẹ́ẹ̀kan síi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,
24. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, ‘Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò ti ní rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú.’
25. Ìdìtẹ̀ sì wà láàrin àwọn ọmọ aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹ̀ran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìsúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀.