26. Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀,
27. Ìparun! Ìparun! Èmi yóò sé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò se pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fifún.’
28. “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọ̀tẹ̀lẹ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nípa àwọn ará Ámónì àti àbùkù wọn:“ ‘Idà kan idà kantí á fa yọ fún ìpànìyàntí a dán láti fi ènìyàn ṣòfòàti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!
29. Bí ó tilẹ jẹ́ pé a rì èké nípa yínàti àfọ̀sẹ èké nípa yína yóò gbé e lé àwọn ọrùnènìyàn búburú ti a yóò pa,àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.
30. Dá idà padà sínú akọ rẹ̀Níbi tí a gbé sẹ̀dá yín,ní ibi tí ẹ̀yin ti sẹ̀ wá.