14. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,sọ tẹ́lẹ̀ kí ó sì fí ọwọ́ lu ọwọ́Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta.Ó jẹ́ idà fún ìpànìyànidà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀Tí yóò sé wọn mọ́ níhìnín àti lọ́hùnnún.
15. Kí ọkàn kí ó lè yọ́kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparunÁà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,a gbá a mú fún ìparun.
16. Ìwọ idà, jà sí ọ̀túnkí o sì jà sí òsìlọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ
17. Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”
18. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:
19. “Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fín idà ọba Bábílónì láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkòríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.
20. La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọ lu Rábà ti àwọn ará Ámónì kí òmíràn kọ lu Júdà, kí ó sì kọ lu Jérúsálẹ́mù ìlú olódi.
21. Nítorí ọba Bábílónì yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti wá àmìn nǹkan tí ń bọ̀: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò bèèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.