30. “Nítorí náà sọ fún ile Ísírẹ́lì: ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ṣe o fẹ bara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, to ń ṣe àgbèrè nípa tí tẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra?
31. Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, irúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú wọn la iná kọjá-ẹ ń tèṣíwájú láti bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, èmi ó wa jẹ ki ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi bí ilé Ísírẹ́lì? Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, N kò ní i jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.
32. “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ dàbí àwọn orílẹ̀ èdè yóòkù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá.
33. Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, ń ó jọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí ń ó nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.