8. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’
9. “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.
10. Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátapáta nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn bá kọ lù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”