Ísíkẹ́lì 16:54-63 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

54. Kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ se láti tù wọ́n nínú.

55. Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ; Samaríà àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ.

56. Iwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sódómù ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ,

57. Kó tó di pé àsírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Édómù Síríà àti gbogbo agbègbè rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Fílístínì àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, ti wọn si ń kẹ́gàn rẹ.

58. Èmi yóò gba ẹ̀san ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìríra rẹ ní Olúwa wí.

59. “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi yóò hùwà sí ọ gẹ́gẹ́ bi ó ṣe tọ́ sí ọ, nítorí o ti kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dídà májẹ̀mú.

60. Síbẹ̀ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ ṣe nígbà ewe rẹ, èmi yóò sì bá ọ dá májẹ̀mú láéláé.

61. Nígbà náà ni ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ ojú yóò sì tì ọ́ nígbà tí mo bá gba àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ obìnrin padà: Fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá.

62. Èmi yóò gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì mọ pé èmi ni Olúwa.

63. Nígbà tí mo bá sì ti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tan, Èmi yóò sì rántí ojú yóò tì ọ́, ìwọ kò sì ní le ya ẹnu rẹ mọ́ nítorí ìtìjú rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”

Ísíkẹ́lì 16