50. Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi iwọ ti ròó, nítorí ìgbéraga àti àwọn Ohun ìríra tí wọ́n ṣe.
51. Samaríà kò ṣe ìdájìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arabìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe.
52. Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Torí náà rú ìtíjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.
53. “ ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ padà ìgbèkùn àti Samaríà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ, èmi yóò sì dá ìgbèkùn tirẹ̀ náà padà pẹ̀lú wọn