42. Nígbà náà ni ìbínú mi sí Ọ yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ, èmi kò sì ní bínú mọ́.
43. “ ‘Nítorí pé o kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sórí rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ?
44. “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.”
45. Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ. Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì.
46. Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaríà, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá aríwá rẹ, Sódómù sì ni àbúrò rẹ, obìnrin tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ ni ìhà gúúsù rẹ.