4. ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tó ó gbé òrìṣà sí ọkàn wọn, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ ṣíwájú rẹ̀, bá wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi Olúwa fúnra mi ni n ó dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ.
5. N ó ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Ísírẹ́lì tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’
6. “Nítorí náà sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ẹ ronú pìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀!
7. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sọ́kàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó ń mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣíwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi Olúwa fúnra ara mi ní ń o dá a lóhùn.