Ísíkẹ́lì 13:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?

8. “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín: ni Olúwa Ọlọ́run wí.

9. Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké. Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run.

10. “ ‘Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi sìnà, wọ́n ní, “Àlàáfíà” nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún,

11. nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ̀ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, N ó sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀.

12. Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn ò ní bi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?”

Ísíkẹ́lì 13