Ísíkẹ́lì 12:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

18. “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ̀n rìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà.

19. Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí; fún àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé: Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn ó máa jẹun wọn, wọn ó sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀.

20. Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

Ísíkẹ́lì 12