Ísíkẹ́lì 11:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrin ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà oòrùn ìlú náà.

24. Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi lójú ìran lọ bá àwọn ìgbèkùn Bábílónì. Ìran tí mo rí sì parí,

25. Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní Ìgbèkùn.

Ísíkẹ́lì 11