26. Lókè àwọ̀ òfuurufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta Sáfírè, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà.
27. Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká.
28. Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú ìkuukùu nígbà tí òjò bá rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká.Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.