16. Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba: mo sì gbọ́ iye wọn.
17. Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jàkìntì, àti tí súfúrù: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìninún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti súfúrù tí ń jáde.
18. Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ̀ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa súfúrù tí o ń tí ẹnu wọn jáde.
19. Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: Nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pani lára.