Ìfihàn 9:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Wọ́n ní ańgẹ́lì ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù ní Ábádónì, àti ni èdè Gíríkì orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Àpólíónì.

12. Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.

13. Ańgẹ́lì kẹ́fà si fún, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run.

14. Òun wí fún ańgẹ́lì kẹ́fà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Yúfúrátè!”

15. A sì tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèṣè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àtí oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ̀ta ènìyàn.

16. Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba: mo sì gbọ́ iye wọn.

17. Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jàkìntì, àti tí súfúrù: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìninún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti súfúrù tí ń jáde.

18. Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ̀ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa súfúrù tí o ń tí ẹnu wọn jáde.

19. Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: Nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pani lára.

20. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́ràn, tàbí kí wọn rìn:

21. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbérè wọn, tàbí olè wọn.

Ìfihàn 9