Ìfihàn 9:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún.

11. Wọ́n ní ańgẹ́lì ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù ní Ábádónì, àti ni èdè Gíríkì orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Àpólíónì.

12. Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.

13. Ańgẹ́lì kẹ́fà si fún, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run.

14. Òun wí fún ańgẹ́lì kẹ́fà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Yúfúrátè!”

15. A sì tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèṣè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àtí oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ̀ta ènìyàn.

16. Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba: mo sì gbọ́ iye wọn.

17. Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jàkìntì, àti tí súfúrù: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìninún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti súfúrù tí ń jáde.

Ìfihàn 9