8. Láti inú ẹ̀yà Sebulúnì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Jósẹ́fù a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.
9. Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn.
10. Wọn sì kígbe ni ohùnrara, wí pé:“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wátí o jókòó lórí ìtẹ́,àti ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn!”