Ìfihàn 5:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn ańgẹ́lì púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárun ọ̀nà ẹgbàarún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.

12. Wọn ń wí lóhùn rara pé:“Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà tí a tí pa,láti gba agbára,àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,àti ògo, àti ìbùkún.”

13. Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,“Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntànnáà láé àti láéláé.”

14. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé.

Ìfihàn 5