Ìfihàn 4:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsí i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run: Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ̀yìn èyí hàn ọ́.”

2. Lójú kan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsí i, a tẹ́ ìtẹ́ kan lọ́run ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà.

Ìfihàn 4