Ìfihàn 21:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ní ìhá ìlà-oòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu-bodè mẹ́ta; ní ìhà gúsù ẹnu-bodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-òòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta.

14. Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Àpósítélì méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

15. Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ̀, àti odi rẹ̀.

16. Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba.

17. Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ̀ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí ańgẹ́lì náà.

Ìfihàn 21