Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:41-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi i lé wọn lọ́wọ́ láàyè.

42. Èyí sì di mímọ̀ já gbogbo Jópà; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.

43. Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Jópà ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Símónì oníṣọ̀nà-awọ.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9