Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Dámásíkù, ó fi hàn pé, èyí ni Kírísítì náà.

23. Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á

24. Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mímọ̀ fún Ṣọ́ọ̀lù. Wọ́n sì ń sọ́ ẹnu-bodè pẹ̀lú lọ́san àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.

25. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

26. Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù sì de Jerúsálémù ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9