Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sọ́ọ̀lù sì wà níbẹ̀, ó sì ní ohùn sí ikú rẹ̀.Ní àkókò náà, inúnibini ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerúsálémù, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Jùdíà àti Samaríà, àyàfi àwọn àpósítélì.

2. Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Sítéfánù lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀.

3. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rè sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.

4. Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo, wọn ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.

5. Fílípì sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaríà, ó ń wàásù Kírísítì fún wọn.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8