Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Lẹ́yìn èyí, Jósẹ́fù ránsẹ́ pe Jákọ́bù baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ̀dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrúndínlọ́gọ́rin ènìyàn.

15. Nígbà náà ni Jákọ́bù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí.

16. A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣékémù, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Ábúráhámù rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Ámórì ní Sékémù ní iye-owó wúrà kan.

17. “Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Ábúráhámù sẹ kù dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbérù si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Íjíbítì.

18. Ṣùgbọ́n ọba mị̀íràn, ẹni tí kò mọ ohunkóhun nípa Jósẹ́fù, di alásẹ lórí ilẹ̀ Íjíbítì.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7