Ìṣe Àwọn Àpósítélì 6:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùn-sínú wà ní àárin àwọn Gíríkì tí se Júù àti àwọn Hébérù tí se Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.

2. Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábílì.

3. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí.

4. Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 6