Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. “Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn Kèfèrì wọ́n ó sì gbọ́.

29. Nígbà tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn tan, àwọn Júù lọ, wọ́n bá ara wọn jíyàn púpọ̀.”

30. Pọ́ọ̀lù sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.

31. Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jésù Kírísítì Olúwa, ẹnìkan kò dá a lẹ́kun.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28