7. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí ì gbà. Ọba, n ítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn.
8. Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?
9. “Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jésù tí Násárétì.
10. Èyi ni mo sì ṣe ni Jerúsálémù. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i.
11. Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú ṣínágọ́gù dé inú ṣínágọ́gù, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì ṣí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.