Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àgírípà sì wí fún Pọ́ọ̀lù pé, “A fún ọ láàyè láti sọ tí ẹnu rẹ.” Nígbà náà ní Pọ́ọ̀lù ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé:

2. “Àgírípà ọba, inú èmi tìkárami dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi mi sùn,

3. pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrin àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fí sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.

4. “Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerúsálémù.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26