28. Olórí-Ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.”Pọ́ọ̀lù wí pé, “Ṣùgbọn a bí mi sínú rẹ̀ ni.”
29. Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Ọlórí-ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní Pọ́ọ̀lù i ṣe, àti nítorí ó tí dè é.
30. Ní ijọ́ kéjì, nítorí tí olórí-ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Pọ́ọ̀lù sùn sí, ó túu sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró ní wájú wọn.