Ìṣe Àwọn Àpósítélì 22:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Nígbà tí mo padà wá sí Jerúsálémù tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹ́ḿpílì, mo bọ́ sí ojúran,

18. mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerúsálémù kán-kán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’

19. “Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú sínágọ́gù kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 22