Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:36-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà.

37. Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

38. Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20