Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ṣùgbọn èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó sọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jésù Olúwa, láti máa ròyìn ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọ̀lọ́run.

25. “Ǹjẹ́ nísìnsìn yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrin ẹni tí èmi tí ń kiri wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́.

26. Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúró nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.

27. Nítorí tí èmi kò fà ṣẹ́yìn láti ṣọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20