Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù:

20. Bí èmí kò ti fà ṣẹ́yìn láti sọ ohunkohun tí ó ṣàǹfàànì fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.

21. Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Gíríkì pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.

22. “Ǹjẹ́ nsṣinsìn yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerúsálémù, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀:

23. Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi.

24. Ṣùgbọn èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó sọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jésù Olúwa, láti máa ròyìn ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọ̀lọ́run.

25. “Ǹjẹ́ nísìnsìn yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrin ẹni tí èmi tí ń kiri wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20