Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkarayín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Éṣíà, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà.

19. Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù:

20. Bí èmí kò ti fà ṣẹ́yìn láti sọ ohunkohun tí ó ṣàǹfàànì fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.

21. Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Gíríkì pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20