Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. “Ará, èmí lè sọ fún yin pẹ́lú ìgboyà pé ní ti Dáfídì baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí.

30. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

31. Ní rírí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kírísítì, pé a kò fi ọkan rẹ̀ sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.

32. Jésù náà yìí ni Ọlọ́run ti jí díde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.

33. A ti gbé ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsìyìí sítá.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2