39. Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́.
40. Nítorí àwa ṣa wà nínú èwu, nítórí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lóní yìí; kò sáá ní ìdí kan tí ìwọ́jọ yìí fi bẹ́ sílẹ̀.”
41. Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.