Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19:24-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Démétíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé-òrìṣà fún Dáyánà, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà;

25. Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nipa iṣẹ́-ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.

26. Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.

27. Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”

28. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù!”

29. Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò.

30. Nígbà ti Pọ́ọ̀lù sì ń fẹ́ wọ àárin àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un.

31. Àwọn olórí kan ara Éṣíà, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ibi-ìṣeré náà.

32. Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíran: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọ pọ̀.

33. Àwọn kan nínú àwujọ ń gún Alekisáńdérù, tí àwọn Júù tì síwájú, ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣọ̀rọ̀ Alekisáńdérù sì juwọ́ sì wọn, òun ìbá sì wí ti ẹnu rẹ̀ fún àwọn ènìyàn.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19