Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí tí òun náà jẹ́ onísẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì nṣíṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́-ọwọ́ wọn.

4. Ó sì ń fọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ fún wọn nínú ṣínágógù lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Gíríkì lọ́kàn padà.

5. Nígbà tí Sílà àti Tímótíù sì tí Makedóníà wá, ọ̀rọ̀ náà ká Pọ́ọ̀lù lára, ó ń fi hàn fún àwọn Júù pé, Jésù ni Kírísítì náà.

6. Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn èmi mọ́: láti ìsinsìnyìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18