Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àwọn wọ̀nyí sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalóníkà lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé-mímọ̀ lójoojúmọ́ bí ǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀.

12. Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Gíríkì ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin, kì í ṣe díẹ̀.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalóníkà mọ̀ pé, Pọ́ọ̀lù ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Béreóà, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè.

14. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Pọ́ọ̀lù jáde lọ́gán láti lọ títí de òkun: ṣùgbọ́n Sílà àti Tímótíù dúró ṣíbẹ̀.

15. Àwọn tí ó sin Pọ́ọ̀lù wá sì mú un lọ títí dé Átẹ́nì; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sílà àti Tímótíù pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17