Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15:39-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Bánábà sì mu Máàkù ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Sáípúrọ́sì.

40. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.

41. Ó sì la Síríà àti Kílíkíà lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15